These two individuals we believe embody what it is to be a Gbajumo in this day and age."
Watch Here
YORUBA |
ENGLISH |
Hmm, Gbajúmọ̀. Adé orí la fi ń m'Ọba ní tòótọ́, ìlẹ̀kẹ̀ la fi ń mọ àwọn ìjòyè, Àpẹẹrẹ tẹ rí n la fi ń mọ aláróbo. Hmm, Sèbi ní ìgbà ìwásè: Bi igba oju bá le mọ́ ẹ̀dá alàyè kan tí onítòhún kì í ṣe ọba ìlú tàbí jagunjagun tó gbójú gbóyà, a jẹ́ wí pé Gbajúmọ ni onítọ̀hún, Ọlogbòn, Ẹni iyì, Ẹni ẹ̀yẹ, Ṣè b'ẹ́ni àpọ̀nlé ni gbajúmọ̀ jé̩. Ẹni igba ojú mọ̀, Gbajúgbajà, Ẹni pàtàkì. Ẹni lágbájá mọ̀, Tí tàmẹ̀dò mọ̀, Títí tó fi dórí ọba ìlú. Ìlúmọ̀ọ́ká. Gbajúmọ̀ ènìyàn won po, Ęlẹ́wà àbi ìwà tútù bí àdàbà, Ó fi ìwà kẹ́wà, Ó wá fi gbogbo àrà hun ni. Ẹwà níní p’ọgbọ́n ooo, Mo ní ẹwà níní yàtọ̀ síra wọn, Àtọwọ́dá, ó yàtọ̀ sámó̩dá, Àmúntọ̀run wá yàtọ̀ sí ká f'epo para. ìwà àti ẹwà: àwọn méjéèjì á ma wà ni. Sùgbọ́n ìwá gangan ni gbajúmọ̀ Gbajúmọ̀ ò lẹ́wà. Ó yọ gedege, O da gòjò gòjò, Ó fi títù mìmì jọ̀jọ̀ tayọ gbogbo Ęgbẹ́ rẹ̀. Ojú tó r’éégún, Tó r’órò, Tójú náà ò tí ì rí gẹ̀lẹ̀dẹ́, Ojú náà ò tí ì rí nkan kan, Èyí tó túmọ̀ sí wí pé: Ojú tóòrí gbajúmọ̀ láwùjọ kò rí nǹkan kan. Hmm, Ẹ bámi pe ìkórera kó wo, Gbajúmọ̀, Arìn bi ẹni ẹ̀gbẹ́ ń dùn, Égbẹ́ ò kúkú dùn ún, Olọ́tẹ̀ ní ń ruga sí. Bí gbajúmọ̀ báyọ, Wọ́n ma ki lọ́tùn ún, Wọ́n ma ki lósì, Wọ́n ma gbe gẹ̀gẹ̀gẹ̀, Bí i ẹyin. Yorùbá bò̩;wọ́n ní: Gbajúmọ̀ kì í wá nkan tí. Bi a bá ti l’órúkọ tán, À kì í wá 'kì kún un. T’ ẹrú t'ọmọ ní i fẹ́ràn Gbajúmọ̀, Bó ti ń f'óní tọ́rọ́ ní tọ́rọ́, a sì fún oní kọ́bò̩ bí ipa rẹ̀ ti mọ. Hmm. Ọlá a máa ṣí lọ nílé ẹni, Ẹwà a sì tipa àìsàn di àbùkùn, Olówó òní lè d'olòṣì bó dọ̀la. Òkùn lọlá, Òkùn ni ibi ọrọ̀, Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣí lọ ní ilé ẹni. Ìwà nìkan ní í báni dé sàréè, Ìwà kò sí, Ẹ̀kọ́ degbé, Gbajúmọ̀ sọnù. Ìrẹ́jẹ ò sí nínú fọ́tọ̀ ooo, Bó o bá ti jókòó náà lo ó ṣe bára rẹ. A kì í l'óókọ tán Ká tún wá ki kùnu. Gbajúmọ̀. Gbajúmọ̀ ò lewà, Ó yọ gedege, O da gòjò gòjò, Ó fi títù mìmì jọ̀jọ̀ tayọ gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀. Ojú tó r’éégún, Tó r’órò, Tójú náà ò tí ì rí gẹ̀lẹ̀dẹ́, Ojú náà ò tí ì rí nǹkan kan Ojú tóórí gbajúmọ̀ láwùjọ, Ojú na orí nǹkan kan. Ẹ bámi pe ìkórera kó wo, Gbajúmọ̀, Arìn bi ẹni ẹ̀gbẹ́ ń dùn, Ègbẹ́ ò kúkú dùn ún, Olọ́tẹ̀ ní ń ruga sí o.. Bí gbajúmọ̀ báyọ, Wọ́n ma ki lọ́tùn ún, Wọ́n ma ki lósì, Wọ́n ma gbe gẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ẹyin. Yorùbá bò̩ wọ́n ní; Gbajúmọ̀ kì í wá nkan tí, Bí ó bá ti l’órúkọ tán, À kì í wá 'ki kù, Tẹrú tọmọ ni ń fẹ́ràn Gbajúmọ̀ láwùjọ, Bó tí fún oní tọ́rọ́ ní tọ́rọ́, A sì f'óníkọbọ̀ bi ipa rẹ̀ ti mọ. Olá á ma ṣílọ ní ilé ẹni, Ęwà á sì ti pa àìsàn di àbùkùn, Olówó òní le di olòṣì bó dọ̀la, Òkùn lọlá, Òkùn ni ìgboro, Gbogbo wọn ni wọ́n ṣílọ ní ilé ẹni, Ìwà ni báni dé sàárè, Ìwà kòsí, Eko de’ de, Gbajúmọ̀ sonù. Ìrẹ̀jẹ kò sí nínú fọ́tò ooo, Bó o bá ṣe jókòó, Bẹ́è̩ náà lo ó ṣe ma bára rẹ. A kì í gbórúkọ tán ka tú wá ki kù. |
Hmm, Prominent individual, A king is only truly recognized by the crown, Chiefs are recognized by their beads, People are often addressed by the way they dress. Hmm, In ancient times: If a person is known by all and he’s neither a king, a chief, nor a great warrior, Such person is a prominent individual, A wise person, A humble person, A person worth to be celebrated. A Prominent individualis a well respected person. A person known by the masses, A well know person across globe, An important individual. A person Known by family and friends, And recognised by those he has no knowledge of, Even recognized by the king, Known far and wide. there are a lot of prominent individuals, A person of beauty and calmness as that of a dove The beauty compliments attitude, A flawless craft of Creation. Beauty can be categorized into various types, Yet beauty differs from one another, A cosmetic beauty has no hold on a natural one, A beauty bestowed from the Heavens is different to that of cosmetics, Beauty and character: These two searches for individuals But character itself is what defines Prominent individual Prominent individuals are beautiful, A beauty that glows, A beauty that can’t go unnoticed, his calmness makes him different from his peers. Eyes that has seen masquerade, That has seen órò festival, And the eyes hasn't seen masked dancers, Those eyes haven't seen anything, Which means that: Eyes that hasn't seen a prominent individual in the surrounding hasn't seen anything. Hmm, Help me call disgust to keep a distance, Prominent individual Walking like their ribs hurts, The ribs doesn't hurt, It's the haters that she's showing off to. Once a Prominent individualsurfaces, Greetings are heard from the right, Greetings are heard from the left, The people care for him, Like an egg. In a yoruba adage: Prominent individual gets all he searches and aims for. After earning a name, We do not search for anything else. Both the slaves and the freed express their lovetowards prominent individuals, As he gives alms to the needy, He also helps others who are struggling as much. Hmm. His wealth never diminishes, Her beauty keeps away sickness and bad energy, The wealthy will never get poor even in the future, Wealth is prestige, Wealth is fortune, All virtues are found with them always. Character is the only thing that we will get buried with us all in the end, Without character, There will be no morals, Prominent individuals will cease to exist, There’s no lie in pictures, The way you sit is the way you are captured. We do not earn a good name then lose morals. Prominent individual, A prominent individual is beautiful, A beauty that glows without make up, A beauty that can’t go unnoticed his calmness makes him different from his peers. Eyes that has seen masquerade, That has seen órò festival, And the eyes hasn't seen masked dancers, Those eyes haven't seen anything, Eyes that hasn't seen Prominent individualin thesurrounding Those eyes hasn't seen anything. Help me call disgust to keep a distance, Prominent individual Walking like their ribs hurts, The ribs doesn't hurt, It's the haters that she's showing off to. Once a Prominent individualsurfaces, Greetings are heard from the right, Greetings are heard from the left, The people care for him like an egg. The beautiful gracious strides of a pageant; In a yoruba adage: Prominent individualgets all he searches and aims for. After earning a name, We do not search for anything else. Both the slaves and the freed Show their love an affection to Prominent individual in the community, As he gives alms to the needy, He also helps others who are struggling as much. The wealth never diminishes, Her beauty keeps away sickness and bad energy, The wealthy will never get poor even in the future, Wealth is prestige, Wealth is influence, All virtues are found with them always. Character is the only thing that we will get buried with us all in the end, Without character, There will be no morals, Prominent individual will cease to exist, There’s no lie in pictures, The way you sit, Is the way you are captured. We do not earn a good name then lose morals. |
Credits
Photography: Adebayo Jolaoso
Creative direction: Bella Adeleke